Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:24-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀ta mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.

25. Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà.

26. Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ ṣíbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré.

27. Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.

28. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”

29. Jónátánì sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdàámú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí.

30. Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀ta wọn lónìí, pípa àwọn Fílístínì ìbá ti pọ̀ tó?”

31. Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa nínú àwọn Fílístínì láti Míkímásì dé Áíjálónì, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà.

32. Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀.

33. Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́sẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹrán tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.”Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá síbi nísinsìn yìí.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14