Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 14:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà ni ìbẹ̀rù bojo bá àwọn ọmọ ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

16. Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Sàúlù ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì sì rí àwọn ọmọ ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà.

17. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wòó, Jónátanì àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.

18. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Áhíjà pé, “Gbé àpótí Ọlọ́run wá.” Àpótí Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà náà.

19. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì ń bá àlùfáà sọ̀rọ̀, ariwo ní ibùdó àwọn Fílístínì sì ń pọ̀ ṣíwájú sí. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àlùfáà pé, “Dá ọwọ́ rẹ dúró.”

20. Ṣọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Fílístínì ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkéjì rẹ̀.

21. Àwọn Hébérù tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Fílístínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì.

22. Nígbà tí gbogbo àwọn Ísírẹ́lì tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Éfúráímù gbọ́ pé àwọn Fílístínì sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná.

23. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Ísírẹ́lì ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Bẹti-Áfénì.

24. Gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀ta mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.

25. Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà.

26. Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ ṣíbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré.

27. Ṣùgbọ́n Jónátanì kò gbọ́ pé baba rẹ̀ ti fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ orí ọ̀pá tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bọ afárá oyin náà, ó sì fi sí ẹnu rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dán.

28. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun sọ fún un pé, “Baba rẹ fi ègún kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ogun wí pé, ‘Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ ní òní!’ Ìdí nìyìí tí àárẹ̀ fi mú àwọn ènìyàn.”

29. Jónátánì sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdàámú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 14