Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 13:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàárin àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kàǹga gbígbẹ.

7. Àwọn Hébérù mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jọ́dánì sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.Ṣọ́ọ̀lù wà ní Gílígálì ṣíbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù.

8. Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Sámúẹ́lì dá; ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn ènìyàn Ṣọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká.

9. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi,” Ṣọ́ọ̀lù sì rú ẹbọ sísun náà.

10. Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ náà, Sámúẹ́lì sì dé, Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti lọ kí i.

11. Sámúẹ́lì sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Fílístínì sì kó ara wọ́n jọ ní Míkímásì,

12. mo rò pé, ‘Àwọn Fílístínì yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gílígálì nísinsìn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipa láti rú ẹbọ sísun náà.”

13. Sámúẹ́lì sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé.

14. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

15. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì kúrò ní Gílígálì, ó sì gòkè lọ sí Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, Ṣọ́ọ̀lù sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.

16. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, nígbà tí àwọn Fílístínì dó ní Míkímásì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 13