Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 13:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

15. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì kúrò ní Gílígálì, ó sì gòkè lọ sí Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, Ṣọ́ọ̀lù sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.

16. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gíbéà ti Bẹ́ńjámínì, nígbà tí àwọn Fílístínì dó ní Míkímásì.

17. Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Fílístínì ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ófírà ní agbégbé ìlú Ṣúálì.

18. Òmíràn gba ọ̀nà Bẹti-Hórónì, ẹ̀kẹ́ta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Ṣébóímù tí ó kọjú sí ijù.

19. A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí tí àwọn Fílístínì wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Hébérù yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!”

20. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Ísírẹ́lì tọ àwọn Fílístínì lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ̀ wọn.

21. Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdásímẹ́ta ṣékélì, àti ìdásímẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n ọ̀yà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 13