Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 10:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nísinsìn yìí, arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì.

15. Arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Sámúẹ́lì wí fún un yín.”

16. Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Sámúẹ́lì sọ nípa ọba jíjẹ.

17. Sámúẹ́lì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí iwájú Olúwa ní Mísípà.

18. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Èmi mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Éjíbítì àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’

19. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20. Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

21. Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì. Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,

22. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrin àwọn ẹrù.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 10