Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 1:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa alágbára jùlọ ní Ṣílò, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.

4. Nígbàkígbà tí ó bá kan Elikánà láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Pẹ̀nínà àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin.

5. Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hánà nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú.

6. Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín in níràn láti lè mú kí ó bínú.

7. Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hánà bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín-in níràn títí tí yóò fi máa sunkún tí kò sì ní lè jẹun.

8. Elikánà ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hánà èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”

9. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣílò, Hánà dìde wá ṣíwájú Olúwa. Nígbà náà, Élì àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó.

10. Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hánà sunkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

11. Ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ wí pé, “Olúwa alágbára jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́-bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí iwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”

12. Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Élì sì kíyèsí ẹnu rẹ̀.

13. Hánà ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Élì rò wí pé ó ti mu ọtí yó.

14. Ó sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 1