Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 1:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Hánà dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.

16. Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”

17. Élì dáhùn pé, “Má a lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

18. Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọbinrin náà bá tirẹ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.

19. Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà: Elikánà si mọ aya rẹ̀: Olúwa sì rántì rẹ̀.

20. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, pé, “Nítorí tí mo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”

21. Ọkùnrin náà Elikánà, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rúbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

22. Ṣùgbọ́n Hánà kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”

23. Elikánà ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa ṣáà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.

24. Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun éfà kan, àti ìgò ọti-wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣílò: ọmọ náà ṣì wà ní ọmọdé.

25. Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Élì wá.

26. Hánà sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láàyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa.

27. Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi.

28. Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fí i fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa nibẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 1