Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 8:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí-ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí-ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e.

8. Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti ibi mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde ibi mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

9. Kò sí ohun kankan nínú àpótí-ẹ̀rí bí kò ṣe tábìlì òkúta méjì tí Mósè ti fi sí ibẹ̀ ní Hórébù, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10. Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́, àwọ̀sánmà sì kún ilé Olúwa.

11. Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọ̀sánmà náà, nítorí ògo Olúwa kún ilé náà.

12. Nígbà náà ni Sólómónì sì wí pé, “Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri;

13. Nítòótọ́ èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.”

14. Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn.

15. Nígbà náà ni ó wí pé:“Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,

16. ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dáfídì láti ṣàkóso àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

Ka pipe ipin 1 Ọba 8