Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 8:61-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

61. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.”

62. Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Ísírẹ́lì rú ẹbọ níwájú Olúwa.

63. Sólómónì rú ẹbọ ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbàá mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn omọ Ísírẹ́lì ya ilé Olúwa sí mímọ́.

64. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárin tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ọrẹ ṣíṣun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.

65. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe àpèjọ nígbà náà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hámátì títí dé odò Éjíbítì. Wọ́n sì sàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ijọ́ méje àti ijọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.

66. Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 8