Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 6:23-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ní inú-ibi-mímọ́ jùlọ ni ó fi igi ólífì ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga.

24. Apá kérúbù kìn-ní-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì.

25. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèje jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà.

26. Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.

27. Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́-apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrin yàrá náà.

28. Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29. Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù síi àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko.

30. Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31. Nítorí ojú ọ̀nà ibi-mímọ́-jùlọ ni ó ṣe ilẹ̀kùn igi ólífì sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri.

32. Àti lára ilẹ̀kùn igi ólífì náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ.

33. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi ólífì onígun mẹ́rin fún ilẹ̀kùn ilé náà.

34. Ó sì tún fi igi fírì ṣe ilẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀.

35. Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.

36. Ó sì fi ẹṣẹṣẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹṣẹ kan ìtí kédárì kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.

37. Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lé ilẹ̀, ní oṣù Sífì.

38. Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Búlù, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.

Ka pipe ipin 1 Ọba 6