Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 6:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀.

21. Sólómónì sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó.

22. Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

23. Ní inú-ibi-mímọ́ jùlọ ni ó fi igi ólífì ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga.

24. Apá kérúbù kìn-ní-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì.

25. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèje jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà.

26. Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.

27. Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́-apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrin yàrá náà.

28. Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29. Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù síi àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko.

30. Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.

31. Nítorí ojú ọ̀nà ibi-mímọ́-jùlọ ni ó ṣe ilẹ̀kùn igi ólífì sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri.

32. Àti lára ilẹ̀kùn igi ólífì náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 6