Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 5:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Hírámù ọba Tírè sì gbọ́ pé a ti fi òróró yan Sólómónì ní ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Sólómónì, nítorí ó ti fẹ́ràn Dáfídì ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

2. Sólómónì sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hírámù pé:

3. “Ìwọ mọ̀ pé Dáfídì bàbá mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀ rẹ̀.

4. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe.

5. Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dáfídì bábá mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

6. “Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi Kédárì Lébánónì fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Ṣídónì.”

7. Nígbà tí Hárámù sì gbọ́ iṣẹ́ Sólómónì, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dáfídì ní ọlọgbọ́n ọmọ láti sàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 5