Nígbà tí Hírámù ọba Tírè sì gbọ́ pé a ti fi òróró yan Sólómónì ní ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Sólómónì, nítorí ó ti fẹ́ràn Dáfídì ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.