Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 4:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ọlọ́run sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòrò òye tí a kò le è fi wé iyanrìn tí ó wà létí òkun.

30. Ọgbọ́n Sólómónì sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Éjíbítì lọ.

31. Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Étanì, ará Ésírà, àti Hémánì àti Kálíkólì, àti Darà àwọn ọmọ Máhólì lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀ èdè yíká.

32. Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005).

33. Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.

34. Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀ èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómónì, tí àwọn ọba ayé ń rán, tí ó ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Ọba 4