Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 4:22-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Oúnjẹ Sólómónì fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n (30) ìyẹ̀fun kíkúná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun,

23. Màlúù mẹ́wàá (10) tí ó sanra, àti ogún (20) màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti egbin, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.

24. Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri.

25. Nígbà ayé Sólómónì, Júdà àti Ísírẹ́lì, láti Dánì títí dé Béríṣébà, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.

26. Sólómónì sì ní ẹgbàajì (40,000) ilé ẹsin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàafà (12,000) ẹlẹ́sin.

27. Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Sólómónì ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá síbi tábìlì ọba, wọ́n sì ríi pé ohun kankan kò ṣẹ́ kù.

28. Wọ́n tún máa ń mú ọkà báálì àti kóríko fún ẹsin àti fún ẹsin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.

29. Ọlọ́run sì fún Sólómónì ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòrò òye tí a kò le è fi wé iyanrìn tí ó wà létí òkun.

30. Ọgbọ́n Sólómónì sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Éjíbítì lọ.

31. Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Étanì, ará Ésírà, àti Hémánì àti Kálíkólì, àti Darà àwọn ọmọ Máhólì lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀ èdè yíká.

32. Ó sì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (3,000) òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún (1,005).

33. Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.

Ka pipe ipin 1 Ọba 4