Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:27-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà.

28. Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Árámù rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

29. Wọ́n sì dó ṣíwájú ara wọn fún ọjọ́ méje, àti ní ọjọ́ keje, wọ́n pàdé ogun. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa ọ̀kẹ́ márùn ún (100,000) ẹlẹ́sẹ̀ nínú àwọn ará Árámù ní ọjọ́ kan.

30. Àwọn tókù sì sá àsálà lọ sí Áfékì, sínú ìlú tí odi ti wó lù ẹgbàámẹ́talá-lé ẹgbẹ̀rún nínú wọn. Bẹni-Hádádì sì sá lọ sínú ìlú, ó sì fara pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.

31. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”

32. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, Wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́kí èmi kí ó yè.’ ”Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láàyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”

33. Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹni-Hádádì arákùnrin rẹ.”Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Bẹni-Hádádì jáde tọ̀ ọ́ wá, Áhábù sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.

34. Bẹni-Hádádì sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Dámáskù, bí baba mi ti ṣe ní Samáríà.”Áhábù sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 20