Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì wí:

3. Sílífà àti wúrà rẹ tèmi ni, àti àwọn tí ó dára jùlọ nínú àwọn aya re àti àwọn ọmọ rẹ tèmi ni wọ́n.”

4. Ọba Ísírẹ́lì sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe wí Olúwa mi ọba, èmi àti ohun gbogbo tí mo ní tìrẹ̀ ni.”

5. Àwọn ońṣẹ́ náà sì tún padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Bẹni-Hádádì sọ wí pé: ‘Mo ránṣẹ́ láti béèrè fún fàdákà rẹ àti wúrà rẹ, àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ.

6. Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”

7. Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”

8. Àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má se fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí o gbà fún un.”

9. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, “Sọ fún Olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì.

10. Bẹni-Hádádì sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Áhábù wí pé, “kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eekuru Samáríà yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”

11. Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé: ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́rà halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”

12. Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ tẹgun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.

13. Sì kíyèsí i, wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin 1 Ọba 20