Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 2:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó ti jọba lórí Ísírẹ́lì ní ogójì ọdún (40): ọdún méje (7) ni Hébúrónì àti ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) ní Jérúsálẹ́mù.

12. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

13. Wàyìí, Àdóníjà ọmọ Hágítì tọ Bátíṣébà, ìyá Sólómónì wá. Bátíṣébà sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.”

14. Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”Bátíṣébà sì wí pé, “Má a wí.”

15. Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Ísírẹ́lì ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá.

16. Nísinsìnyí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mí.”Ó wí pé, “O lè wí.”

17. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀ṣíwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Sólómónì ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Ábíságì ará Súnémù ní aya.”

18. Bátíṣébà sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”

19. Nígbà tí Bátíṣébà sì tọ Sólómónì ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Àdóníjà, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

20. Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi”Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 2