Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 16:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jéhù ọmọ Hánánì wá sí Bááṣà pé:

2. “Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jéróbóámù, ó sì mú kí Ísírẹ́lì ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

3. Nítorí náà, èmi yóò mú Bááṣà àti ile rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jéróbóámù ọmọ Nébátì.

4. Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Bááṣà tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko.”

5. Àti ìyókù ìṣe Bááṣà, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

6. Bááṣà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní Tírísà. Élà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

7. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì wá nípa ọwọ́ Jéhù wòlíì ọmọ Hánánì pẹ̀lú sí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú Olúwa, ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jéróbóámù: àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú.

8. Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Élà ọmọ Bááṣà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba ní Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní Tírísà ní ọdún méjì.

9. Ṣímírì, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Élà sì wà ní Tírísà nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Árísà, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tírísà.

10. Ṣímírì sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Áṣà, ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀.

11. Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Bááṣà pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́.

Ka pipe ipin 1 Ọba 16