Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 15:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀. Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì.

14. Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Áṣà pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.

15. Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa

16. Ogun sì wà láàrin Áṣà àti Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.

Ka pipe ipin 1 Ọba 15