Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 15:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù ọmọ Nébátì, Ábíjà jọba lórí Júdà,

2. ó sì jọba ní ọdún mẹ́ta ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

3. Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbáńlá rẹ̀ ti ṣe.

4. Ṣùgbọ́n, nítorí i Dáfídì Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jérúsálẹ́mù nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀.

5. Nítorí tí Dáfídì ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pa láṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Ùráyà ará Hítì.

6. Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé Ábíjà.

7. Níti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò há kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ogun sì wà láàrin Ábíjà àti Jéróbóámù.

8. Ábíjà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì. Áṣà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

9. Ní ogún ọdún Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Áṣà jọba lórí Júdà,

10. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

11. Áṣà sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe.

12. Ó sì mú àwọn tí ń ṣe panṣágà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.

Ka pipe ipin 1 Ọba 15