Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 14:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.

8. Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi.

9. Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn Ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbémi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.

10. “ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jéróbóámù. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jéróbóámù, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Ísírẹ́lì. Èmi yóò mú ilé Jéróbóámù kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán.

11. Ajá yóò jẹ ẹni Jéróbóámù tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní ìgbẹ́ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. Olúwa ti sọ ọ́!’

12. “Níti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú.

13. Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jéróbóámù, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ilé Jéróbóámù.

14. “Olúwa yóò gbé ọba kan dìde fún ra rẹ̀ lórí Ísírẹ́lì tí yóò ké ilé Jéróbóámù kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsìnyìí.

15. Olúwa yóò kọlu Ísírẹ́lì, yóò sì dà bí a ti ń mi ìyẹ́ nínú omi. Yóò sì fa Ísírẹ́lì tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò, nítorí wọ́n ti rú ìbínú Olúwa nípa ṣíṣe ère òrìṣà.

16. Yóò sì kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jéróbóámù ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀.”

17. Nígbà náà ni aya Jéróbóámù sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tírà. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú.

Ka pipe ipin 1 Ọba 14