Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 14:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bẹ́ẹ̀ ni aya Jéróbóámù sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Áhíjà ní Ṣílò.Áhíjà kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Áhíjà pé, “Kíyèsí i, aya Jéróbóámù ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Áhíjà sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jéróbóámù. Kíló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ.

7. Lọ, sọ fún Jéróbóámù pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórì lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.

8. Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dáfídì, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, iwọ kò dàbí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi.

9. Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn Ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbémi sọ sí ẹ̀yìn rẹ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 14