Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 11:11-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí náà Olúwa wí fún Sólómónì pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmìíràn.

12. Ṣùgbọ́n, nítorí Dáfídì baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ.

13. Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jérúsálẹ́mù tí èmi ti yàn.”

14. Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀ta kan dìde sí Sólómónì, Hádádì ará Édómù ìdílé ọba ni ó ti wá ní Édómù.

15. Ó sì ṣe, nígbà tí Dáfídì wà ní Édómù, Jóábù olórí ogun sì gòkè lọ láti sìn àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Édómù.

16. Nítorí Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Édómù run.

17. Ṣùgbọ́n Hádádì sá lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ará Édómù tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀. Hádádì sì wà ní ọmọdé nígbà náà.

18. Wọ́n sì dìde kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì lọ sí Páránì. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Páránì wá, wọ́n sì lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Fáráò ọba Éjíbítì ẹni tí ó fún Hádádì ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ.

19. Inú Fáráò sì dùn sí Hádádì púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tápénésì, ayaba.

20. Arábìnrin Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Génúbátì, ẹni tí Tápénésì tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Génúbátì ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Fáráò fún ra rẹ̀.

21. Nígbà tí ó sì wà ní Éjíbítì, Hádádì sì gbọ́ pé Dáfídì ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Jóábù olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hádádì wí fún Fáráò pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.”

22. Fáráò sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”Hádádì sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”

23. Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà.

24. Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.

25. Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 11