Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 9:20-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní ìgbà àkọ́kọ́ fíníhásì ọmọ Élíásérì jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀.

21. Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22. Gbogbo Rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní àwọn ìlóró ẹnu ọ̀nà jẹ́ ìgba o lé méjìlá (212). A kòmọ̀-ọ́n fún ìràntí nípa ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní àwọn ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò ìgbàgbọ́ wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Ṣámúẹ́lì aríran.

23. Àwọn àti àtẹ̀lé wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.

24. Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù.

25. Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.

26. Ṣùgbọ́n àwọn olórí olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Léfì ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.

27. Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Olúwa ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.

28. Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Olúwa; wọn a má a kàá nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.

29. Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí òlóòórìn dídùn.

30. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípo tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.

31. Ará Léfì tí a sọ ní Mátítíhíà, àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣálúmì ará kórà ni a yàn sí ìdí dídín àkàrà ọrẹ.

32. Lára àwọn arákùnrin wọn kora wọn wà ní ìdí ṣísètò fún àkàrà tí a máa ń gbé sórí àga tábìlì ní ọjọjọ́ Ìsinmi.

33. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Léfì dúró nínú àgọ́ ilé Olúwa, wọn kò sì se lára isẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń se isẹ́ náà lọ́sán, lóru.

34. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Léfì, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ lẹ́sẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

35. Jélíélì baba Gíbíónì ń gbé ní Gíbíónì.Orúkọ ìyàwó Rẹ̀ a má a jẹ́ Mákà,

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 9