Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 9:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbogbo Ísírẹ́lì ni a kọ lẹ́sẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì.Àwọn ènìyàn Júdà ni a kó ní ìgbẹ̀kùn lọ sí Bábílónì nítorí àìsòótọ́ wọn.

2. Nísìnsìn yìí, àwọn tí ó kọ́ kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì àti àwọn Ìránsẹ́ ilé Olúwa.

3. Àwọn tí ó wá láti Júdà láti Bẹ́ńjámínì àti láti Éfíráímù àti Mánásè tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù jẹ́:

4. Hútayì ọmọ Ámíhúdì, ọmọ Ómírì, Ọmọ Ímírì, ọmọ Bánì, ìran ọmọ Fárésì ọmọ Júdà.

5. Tí ará Ṣílò:Ásáíà àkọ́bí àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

6. Níti ará Ṣérà:JégúélìÀwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

7. Níti ará:Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà; ọmọ Hásénúà;

8. Íbínéíà ọmọ Jéróhámù; Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà; ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà.

9. Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10. Ní ti àwọn àlùfáà:Jédáíà; Jéhóíáríbì; Jákínì;

11. Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 9