Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 8:32-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Pẹ̀lú Míkílótì, tí ó jẹ́ bàbá Ṣíméà. Wọ́n ń gbé lébá ìbátan wọn ní Jérúsálẹ́mù.

33. Mérì jẹ́ baba Kíṣì, Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ṣọ́ọ̀lù baba Jónátanì, Málìkíṣúà, Ábínádábù àti Ésíbálì.

34. Ọmọ Jónátanì:Méríbáì tí ó jẹ́ baba Míkà.

35. Àwọn ọmọ Míkà:Pítónì, Mélékì, Táréà, àti Áhásì.

36. Áhásì jẹ́ bàbá a Jéhóádá, Jéhóádá jẹ́ baba a Álémétì Áṣíméfétì àti Ṣímírì, Ṣímírì sì jẹ́ baba a Móṣà.

37. Móṣà jẹ́ baba a Bínéà; Ráfà sì jẹ́ ọmọ Rẹ̀, Éléásà ọmọ Rẹ̀ àti Áṣélì ọmọ Rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 8