Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6:77-81 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

77. Àwọn ará Mérárì (ìyókù àwọn ará Léfì) gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ẹ̀yà Sébúlúnìwọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78. Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkòwọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì,

79. Kédémótì àti Méfátù, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko, tútù wọn;

80. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gádìwọ́n gba Rámóà ní Gílíádì Máhánáímù,

81. Hésíbónì àti Jáṣérì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 6