Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6:65-73 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

65. Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66. Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn.

67. Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Géṣérì

68. Jókíméámù, Bétì-Hórónì.

69. Áíjálónì àti Gátì Rímónì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70. Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ádérì àti Bíléámù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kóhátítè.

71. Àwọn ará Géríṣónítè gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè wọ́n gba Gólánì ní Básánì àti pẹ̀lú Áṣítarótì, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72. Láti ẹ̀yà Ísákárìwọ́n gba Kádéṣì, Dábérátì

73. Rámótì àti Ánénù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 6