Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6:42-62 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Ọmọ Étanì, ọmọ Ṣímáhì,ọmọ Ṣíméhì,

43. Ọmọ Jáhátì,ọmọ Gérísíónì, ọmọ Léfì;

44. láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Mérárì wà ní ọwọ́ òsì Rẹ̀:Étanì ọmọ Kísì, ọmọ Ábídì,ọmọ Málúkì,

45. Ọmọ Háṣábíáhìọmọ Ámásáyà, ọmọ Hítíkíáhì,

46. Ọmọ Ámíṣì ọmọ Bánì,ọmọ Ṣémérì,

47. Ọmọ Máhílì,ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì,ọmọ Léfì.

48. Àwọn Léfì ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yókù ti Àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.

49. Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ.

50. Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì:Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀,Ábísúà ọmọ Rẹ̀,

51. Búkì ọmọ Rẹ̀,Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,

52. Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,

53. Ṣádókù ọmọ Rẹ̀àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.

54. Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):

55. A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

56. Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.

57. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,

58. Hílénì Débírì,

59. Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

60. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.

61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.

62. Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 6