Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6:20-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ti Gérísómù:Líbínì ọmọkùnrin Rẹ̀, JéhátìỌmọkùnrin Rẹ̀, Ṣímà ọmọkùnrin Rẹ̀,

21. Jóáhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Idò ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣéráhì ọmọkùnrin Rẹ̀àti Jéátéráì ọmọkùnrin Rẹ̀.

22. Àwọn ìran ọmọ Kóhátì:Ámínádábù ọmọkùnrin Rẹ̀, Kóráhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

23. Élikánà ọmọkùnrin Rẹ̀,Ébíásáfí ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

24. Táhátì ọmọkùnrin Rẹ̀, Úríélì ọmọkùnrin Rẹ̀,Úsíáhì ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Rẹ̀.

25. Àwọn ìran ọmọ Élíkánáhì:Ámásáyì, Áhímótì

26. Élíkáná ọmọ Rẹ̀, Ṣófáì ọmọ Rẹ̀Náhátì ọmọ Rẹ̀,

27. Élíábù ọmọ Rẹ̀,Jéríhámù ọmọ Rẹ̀, Élíkáná ọmọ Rẹ̀àti Ṣámúẹ́lì ọmọ Rẹ̀.

28. Àwọn ọmọ Ṣámúẹ́lì:Jóẹ́lì àkọ́bíàti Ábíjà ọmọẹlẹ́ẹ̀kejì.

29. Àwọn ìran ọmọ Mérárì:Máhílì, Líbínì ọmọ Rẹ̀.Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀, Úṣáhì ọmọ Rẹ̀.

30. Ṣíméà, ọmọ Rẹ̀ Hágíáhì ọmọ Rẹ̀àti Ásáíáhì ọmọ Rẹ̀.

31. Èyí ní àwọn ọkùnrin Dáfídì tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sínmìn níbẹ̀.

32. Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33. Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè:Hémánì olùkọrin,ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì,

34. Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù,ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà

35. Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná,ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì,

36. Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì,ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 6