Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Áhítúbì baba Ṣádókù.Ṣádókù baba Ṣálúmù,

13. Ṣálúmù baba Hílíkíyà,Hílíkíyà baba Áṣáríyà,

14. Áṣáríyà baba Ṣéráíà,pẹ̀lú Ṣéráíà baba Jéhósádákì

15. A kó Jéhósádákì lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Júdà àti Jérúsálẹ́mù kúrò ní ìlú nípaṣẹ̀ Nebukadinésárì.

16. Àwọn ọmọ Léfì:Gérísónì, kóhátì àti Mérárì.

17. Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Géríṣónì:Líbínì àti Ṣíméhì.

18. Àwọn ọmọ Kéhátì:Ámírámù, Íṣárì, Hébírónì àti Húsíélì.

19. Àwọn ọmọ Mérárì:Máhílì àti Múṣì.Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Léfì tí a kọ ní ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20. Ti Gérísómù:Líbínì ọmọkùnrin Rẹ̀, JéhátìỌmọkùnrin Rẹ̀, Ṣímà ọmọkùnrin Rẹ̀,

21. Jóáhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Idò ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣéráhì ọmọkùnrin Rẹ̀àti Jéátéráì ọmọkùnrin Rẹ̀.

22. Àwọn ìran ọmọ Kóhátì:Ámínádábù ọmọkùnrin Rẹ̀, Kóráhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

23. Élikánà ọmọkùnrin Rẹ̀,Ébíásáfí ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 6