Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 4:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Júdà:Fárésì, Hésírónì, Kárímì, Húrì àti Ṣóbálì.

2. Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà.

3. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù:Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì

4. Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

5. Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà.

6. Nárà sì bí Áhúsámù, Héférì Téménì àti Háhásítarì. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Nátà.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 4