Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 29:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà àwọn aṣájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀wá àti alákòóṣo ọrọrún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i.

7. Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún talẹ́ntì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (Dáríkì) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá talẹ́ntì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjìdínlógún talẹ́ntì òjíá àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin talẹ́ntì irin.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní ìhámọ́ Jéhíélì ará Géríṣónì.

9. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dáfídì ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.

10. Dáfídì yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé,“Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa,Ọlọ́run baba a wa Ísírẹ́lì,láé àti láéláé.

11. Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìnàti ọlá ńlá àti dídán,nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ.Tìrẹ Olúwa ni ìjọba;a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

12. Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ;ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan.Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àtiláti fi agbára fún ohun gbogbo.

13. Nísinsìn yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ,a sì fi ìyìn fún orúkọ Rẹ̀ tí ó lógo.

14. “Ṣùgbọ́n Ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè fi sílẹ̀ tinútínú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.

15. Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí.

16. Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo pípọ̀ yìí tí àwa ti pèṣè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ Rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo Rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.

17. Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsìn yìí èmi ti ríi pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́.

18. Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì pa ìfẹ́ yìí mọ́ ninú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtọ́ sí ọ.

19. Àti fún ọmọ mi Sólómónì ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 29