Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 26:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà:Láti ọ̀dọ̀ Kórà: Méṣélémíò ọmọ Kórè, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Áṣáfì.

2. Méṣélémíà ní àwọn ọmọkùnrin:Ṣékáríáyà àkọ́bí,Jédíáélì ẹlẹ́ẹ̀kejì,Ṣébádíáyà ẹlẹ́ẹ̀kẹta,Játiníẹ́lì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rin,

3. Élámù ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,Jehóhánánì ẹlẹ́ẹ̀kẹfààti Eliéhóémáì ẹlẹ́ẹ̀keje.

4. Obedi-Édómù ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú:Ṣémáíà àkọ́bí,Jéhóṣábádì ẹlẹ́ẹ̀kejì,Jóà ẹlẹ́ẹ̀kẹta,Ṣákárì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,Nétanélì ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,

5. Ámíélì ẹ̀kẹfà,Ísákárì ẹ̀kejeàti péúlétaì ẹ̀kẹjọ(Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Óbédì Édómù).

6. Ọmọ Rẹ̀ Ṣémáíà ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé bàbá a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.

7. Àwọn ọmọ Ṣémáíà: Ótínì, Refáélì, Óbédì àti Élíṣábádì; àwọn ìbátan Rẹ̀ Élíhù àti Sémákíà jẹ́ ọkùnrin alágbára

8. Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi Édómù; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Àtẹ̀lé Obedi Édómù méjìlélọ́gọ́ta (62) ni gbogbo Rẹ̀.

9. Móésélémíà ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún (18) ni gbogbo wọn.

10. Hósà ará Merà ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣímírì alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i se àkọ́bí, baba a Rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.

11. Hílíkíyà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tábálíà ẹ̀kẹta àti Ṣékárià ẹ̀kẹrin, àwọn ọmọ àti ìbátan Hósà jẹ́ mẹ́talá (13) ni gbogbo Rẹ̀.

12. Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjísẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.

13. Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó.

14. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣélémíáyà, nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣekaríáyà, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 26