Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sátanì sì ru ọkàn Dáfídì sókè láti ka iye Ísírẹ́lì.

2. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì wí fún Jóábù àti àwọn olórí ti àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun, Lọ kí o lọ ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Béríṣébà títí dé Dánì. Kí o sì padà wá sọ fún mi kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.

3. Ṣùgbọ́n Jóábù dá a lóhùn pé Kí Olúwa pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ Olúwa ọba mi, sé gbogbo wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Olúwa ni? Kí ni ó dé tí Olúwa mi ṣe fẹ́ ṣèyí? Kí ni ó de tí yóò fi mú Ísírẹ́lì jẹ̀bi?

4. Ọ̀rọ̀ ọba, bí ó ti wù kí ó rí, borí tí Jóábù. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù kúrò ó sì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù.

5. Jóábù sì sọ iye tí àwọn ajagun ọkùnrin náà jẹ́ fún Dáfídì. Ní gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì jásí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (Mílíọnù kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún) tí ó lè mú idà àti pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́talélógún lé ẹgbàrún ní Júdà.

6. Ṣùgbọ́n Jóábù kó àwọn Léfì àti Bẹ́ńjámínì mọ́ iye wọn, nítorí àsẹ ọba jẹ́ ìríra fún un.

7. Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Ísírẹ́lì.

8. Nígbà náà Dáfídì sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidìgidì nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà òmùgọ̀ gidigidi.

9. Olúwa sì fi fún Gádì, aríran Dáfídì pé.

10. “Lọ kí o lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Èyí ní ohun tí Olúwa sọ: Èmi sì fún ọ ní àwọn àṣàyàn mẹ́ta. Yan ọ̀kan ninú wọn fún mi láti gbé jáde nípa rẹ.’ ”

11. Bẹ́ẹ̀ ni Gádì lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ó sì wí fún pé, “Nǹkan yí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Yan aṣàyàn tìrẹ:

12. Ọdún mẹ́ta ìyàn, oṣù mẹ́ta gbígbá lọ niwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́fà idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-àrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì run.’ Nísinsi yìí ǹjẹ́, ronú bí èmi yóò ti ṣe dá ẹni tí ó rán mi lóhùn.”

13. Dáfídì sì wí fún Gádì pé èmi wà nínú ìyọnu ńlá. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa, nítorí tí àánú Rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.

14. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-àrùn lórí Ísírẹ́lì, ẹgbàá márùndínlógójì (70,000) ènìyàn Ísírẹ́lì sì kú.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21