Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 2:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Húrì ni baba Úrù, Úrù sì jẹ́ baba Bésálélì.

21. Nígbà tí ó yá, Hésírónì sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírì baba Gílíádì (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Ṣégúbù.

22. Ṣégúbù sì jẹ́ bàbá Jáírì, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́talélógún ní ilẹ̀ Gílíádì.

23. (Ṣùgbọ́n Gésúrì àti Árámù sì fi agbára gba Hafoti Jáírì, àti Kénátì pẹ̀lú gbogbo agbégbé Rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 2