Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 19:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò yí, Náháṣì ọba àwọn ará Ámónì kú, ọmọ Rẹ̀ sì rọ́pò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2. Dáfídì rò wí pé Èmi yóò fi inú rere hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí baba a Rẹ̀ fi inú-rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí Hánúnì níti baba a Rẹ̀.Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì wá sí ọ̀dọ̀ Hánúnì ní ilẹ̀ Àwọn ará Ámónì láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí i,

3. Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ámónì sọ fún Hánúnì pé, Ṣé ìwọ rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún Baba rẹ nípa rírán àwọn ọkùnrin sí ọ láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn.? Ṣé àwọn ọkùnrin Rẹ̀ kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti wá kiri àti samí sita orílẹ̀ èdè àti láti bì í ṣubú.

4. Bẹ́ẹ̀ ni Hanúnì fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dáfídì, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárin ìdí Rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.

5. Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin Rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, Dúró ní Jeríkò títí tí irungbọ̀n yín yóò fi hù, Nígbà náà ẹ padà wá.

6. Nígbà tí àwọn ará Ámónì rí i wí pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dáfídì, Hánúnì àti àwọn ará Ámónì rán ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti síríà Náháráímù, Ṣíríà Mákà àti Ṣóbà.

7. Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Mákà pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọmọ ogun Rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Médébà, nígbà tí àwọn ará Ámónì kó jọ pọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 19