Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 17:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Pẹ̀lú ta ni ó dà bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì-orílẹ̀ èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara Rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti lati ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀ èdè kúrò níwáju àwọn ènìyàn Rẹ̀, ẹni tí ó gbà là láti Éjíbítì?

22. Ìwọ se àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.

23. “Nisinsìn yìí, Olúwa, Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti se fún ìransẹ́ rẹ àti ilé Rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti se ìlérí.

24. Kí ó lè di fifi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa, ni Ọlọ́run Isírẹ́lì.’ Ilé ìransẹ́ rẹ Dáfídì sì ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ níwáju rẹ.

25. “Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìransẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ.

26. Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ.

27. Nísinsìn yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìransẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀ṣíwájú ní ojú rẹ; nitorí ìwọ, Olúwa, ti bùkún un, a ó sì bùkun-un títí láéláé.”

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 17