Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 15:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà. Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì.

12. Ó sì fí fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Léfì; ẹ̀yin àti àwọn Léfì ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

13. Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Léfì kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa ya ìbínú Rẹ̀ lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.

14. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Ísírélì.

15. Nígbà náà ni àwọn Léfì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn. Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti paá láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

16. Dáfídì sọ fún àwọn olórí àwọn Léfì láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orin pisalitérì, dùùrù, àti Ṣíḿbálì.

17. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Léfì yan Hámánì ọmọ Jóẹ́lì; àti nínú àwọn arákùnrin Rẹ̀, Ásáfù ọmọ Bérékíà, àti nínú àwọn ọmọ Mérárì arákùnrin wọn, Étanì ọmọ Kúṣáíà;

18. àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Ṣekaríyà, Jásíélì; Ṣémírámótì, Jéhíélì, Únì, Élíféléhù, Míkíméíà, àti àwọn asọ́bodè Obedi-Edomu àti Jélíélì.

19. Àwọn akọrin sì ni Hémánì, Ásáfù, àti Étanì ti àwọn ti kíḿbálì idẹ tí ń dún kíkan;

20. Ṣekaríyà, Ásíélì, Ṣémírámótì, Jẹ́híélì, Únínì, Élíábù, Máséíà àti Beniáyà àwọn tí ó gbọdọ̀ ta láétírì gẹ́gẹ́ bí àlámótì,

21. Àti Mátítíyà, Élíféléhù, Míkínéyà, Obedi-Édómù, Jélíélì àti Ásásíyà ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn goro, láti darí gẹ́gẹ́ bí Ṣémínítì.

22. Kénáníyá orin àwọn ará Léfì ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa Rẹ̀.

23. Bérékíà àti Ékáníyà ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

24. Ṣébéáníá, Jóṣáfátì, Nétanélì, Ámásáyì, Ṣekaríyà, Beniáyà àti Élíásérì ní àwọn àlùfáà, ti o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Édómù àti Jéhíyà ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùsọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

25. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Édómù, pẹ̀lú inú dídùn.

26. Nítori Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Léfì énì tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi sé ìrúbọ.

27. Nísinsìn yìí Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, gẹ́gẹ́ bí akọrin, àti Kenaníyà, ẹnití ó wà ní ìkáwó orin kíkọ àwọn akọrin. Dáfídì sì wọ aṣọ ìgúnwà fun fun.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 15