Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 14:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní Jérúsálẹ́mù Dáfídì mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di bàbá àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.

4. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣámúyà, Ṣóbábù, Nátanì, Ṣólómónì,

5. Íbárì, Élíṣúà, Élífélétì,

6. Nógà, Néfégì, Jáfíà,

7. Élísámà, Bélíádà, àti Élífélétì.

8. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dáfídì ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dáfídì gbọ́ nípa Rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.

9. Nísinsìn yìí àwọn ará Fílístínì ti wá láti gbógun ti àfonífojì Réfáímù;

10. Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Fílístínì lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ̀n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”

11. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn ènìyàn Rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Pérásímù, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dáfídì lórí àwọn ọ̀ta mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Pérásímù.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 14