Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsìn yìí Hírámù àti ọba Tírè rán oníṣẹ́ sí Dáfídì, àti pẹ̀lú igi kédérì pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.

2. Dáfídì sì mọ Ísírẹ̀lì àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì àti pé Ìjọba Rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwon ènìyàn Rẹ̀.

3. Ní Jérúsálẹ́mù Dáfídì mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di bàbá àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.

4. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣámúyà, Ṣóbábù, Nátanì, Ṣólómónì,

5. Íbárì, Élíṣúà, Élífélétì,

6. Nógà, Néfégì, Jáfíà,

7. Élísámà, Bélíádà, àti Élífélétì.

8. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dáfídì ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dáfídì gbọ́ nípa Rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.

9. Nísinsìn yìí àwọn ará Fílístínì ti wá láti gbógun ti àfonífojì Réfáímù;

10. Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Fílístínì lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ̀n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 14