Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 12:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àti Jóélà, àti Ṣébádíà àwọn ọmọ Jéróhámù láti Gédárì.

8. Díẹ̀ lára àwọn ará Gádì yà sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga ní ihà. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di àṣà àti ẹsin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

9. Ésérì sì jẹ́ ìjòyè,Ọbádáyà sì jẹ́ igbékejì akọgun, Élíábù ẹlẹ́kẹ́ta,

10. Míṣimánà ẹlẹ́kẹ́rin, Jeremíà ẹlẹ́ẹ̀kárùn-ún

11. Átaì ẹlẹ́kẹ́fà, Ẹlíélì èkéje,

12. Jóhánánì ẹlẹ́kẹ́jọ Élísábádì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́sàn-án

13. Jeremíàh ẹlẹ́kẹ́wàá àti Mákíbánáì ẹlẹ́kọ́kànlá.

14. Àwọn ará Gádì wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún.

15. Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jọ́dánì ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè Rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà oòrùn àti níhà ìwọ̀ oòrùn.

16. Ìyòókù ará Bẹ́ńjámínì àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Júdà lọ sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 12