Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 12:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà;

30. àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800)

31. Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn (18,000).

32. Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.

33. Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n (50,000);

34. Àwọn ọkùnrin Náfítalì, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) Ọkùnrin tí wọ́n gbé àṣà àti ọ̀kọ̀ wọn.

35. Àwọn ọkùnrin Dánì, tí wọ́n setan fún ogun ẹgbàámẹ́talá (28,600)

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 12