Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 12:26-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Àwọn ọkùnrin Léfì ẹgbàájì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600),

27. Pẹ̀lú Jéhóíádà, olórí ìdílé Árónì pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn (3,700),

28. Àti Sádókì akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn (22) méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Rẹ̀;

29. Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà;

30. àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800)

31. Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn (18,000).

32. Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.

33. Àwọn ọkùnrin Ṣébúlúnì, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú orísirísi ohun èlò ìjà, láti ran Dáfídì lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàámẹ́dọ́gbọ̀n (50,000);

34. Àwọn ọkùnrin Náfítalì, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) Ọkùnrin tí wọ́n gbé àṣà àti ọ̀kọ̀ wọn.

35. Àwọn ọkùnrin Dánì, tí wọ́n setan fún ogun ẹgbàámẹ́talá (28,600)

36. Àwọn ọkùnrin Áṣérì, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ sójà múra fún ogun ọ̀kẹ́ méje (40,000).

37. Lati ìlà òrùn Jódánì, ọkùnrin Réubénì, Gádì, àti ìdájì ẹ̀yà Mánásè, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000).

38. Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hébrónì tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dáfídì jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n sì jẹ́ onínú kan láti fi Dáfídì jọba

39. Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèṣè oúnjẹ fún wọn.

40. Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jínjìn gẹ́gẹ́ bí Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Náfítanì gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáákà àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èṣo àjàrà gbígbẹ, èṣo ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 12