Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 12:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì):

3. Áhíésérì Olórí wọn àti Jóáṣì àwọn ọmọ Ṣémà ará Gíbéà: Jésíélì àti pélétì ọmọ Ásímáfétì, Bérákà, Jéhù ará Ánátótì.

4. Àti Íṣímáyà ará Gíbíónì, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremáyà, Jáhásíélì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà,

5. Élúsáì, Jérímótì, Béálíà, Ṣémáríà àti Ṣéfátíyà ará Hárófì;

6. Élíkánà, Íṣái, Ásárélì, Jóésérì àti Jáṣóbéà ará kórà;

7. Àti Jóélà, àti Ṣébádíà àwọn ọmọ Jéróhámù láti Gédárì.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 12