Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 12:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dáfídì ní Ṣíkílágì Nígbà tí ó sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kísì (Wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn-án lọ́wọ́ láti ibi ìjà;

2. Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì):

3. Áhíésérì Olórí wọn àti Jóáṣì àwọn ọmọ Ṣémà ará Gíbéà: Jésíélì àti pélétì ọmọ Ásímáfétì, Bérákà, Jéhù ará Ánátótì.

4. Àti Íṣímáyà ará Gíbíónì, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremáyà, Jáhásíélì, Jóhánánì, Jósábádì ará Gédérà,

5. Élúsáì, Jérímótì, Béálíà, Ṣémáríà àti Ṣéfátíyà ará Hárófì;

6. Élíkánà, Íṣái, Ásárélì, Jóésérì àti Jáṣóbéà ará kórà;

7. Àti Jóélà, àti Ṣébádíà àwọn ọmọ Jéróhámù láti Gédárì.

8. Díẹ̀ lára àwọn ará Gádì yà sọ́dọ̀ Dáfídì ní ibi gíga ní ihà. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di àṣà àti ẹsin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

9. Ésérì sì jẹ́ ìjòyè,Ọbádáyà sì jẹ́ igbékejì akọgun, Élíábù ẹlẹ́kẹ́ta,

10. Míṣimánà ẹlẹ́kẹ́rin, Jeremíà ẹlẹ́ẹ̀kárùn-ún

11. Átaì ẹlẹ́kẹ́fà, Ẹlíélì èkéje,

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 12