Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 11:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Ísírẹ́lì ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùsọ́ àgùntàn fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”

3. Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dáfídì ni Hébúrónì. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hébúrónì níwájú Olúwa, wọ́n sì fi àmìn òróró yan Dáfídì ọba lórí Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì.

4. Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jérúsálẹ́mù (tí se Jébúsì) Àwọn ara Jébúsì ẹni tí ń gbé níbẹ̀.

5. Wí fún Dáfídì pé, ìwọ kò sì gbọdọ̀ rí nínú ibẹ̀. Bí ó ti lẹ̀jẹ́ wí pé, Dáfídì kọ lu odi alágbára ti Ṣíónì, ìlú ńlá Dáfídì.

6. Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

7. Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì.

8. Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri. Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 11