Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin.