Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà.